O. Daf 65:1-13

O. Daf 65:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ. Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀. Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro. Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ. Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun. Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure: Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia. Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀. Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃. Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀. Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ. Papa-tutù aginju nkán: awọn òke kekèke fi ayọ̀ di ara wọn li àmure. Agbo ẹran li a fi wọ̀ pápá-tútù na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nhó fun ayọ̀, nwọn nkọrin pẹlu.

O. Daf 65:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni, ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún, ìwọ tí ń gbọ́ adura! Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa, ìwọ a máa dáríjì wá. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn, tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, láti máa gbé inú àgbàlá rẹ. Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn, àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ! Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn, Ọlọrun olùgbàlà wa. Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé, ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀; tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè. O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́, ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀; o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan. Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rù nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ; o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀. Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín, o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú; o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun, o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀. O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ, o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀; o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀, o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà. O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún; gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko. Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀, ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ, ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì, wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀.

O. Daf 65:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni; sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà, gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ. Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò. Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ! A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ, ti tẹmpili mímọ́ rẹ. Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo, Ọlọ́run olùgbàlà wa, ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun, Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ, tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́ ríru ariwo omi wọn, àti ìdágìrì àwọn ènìyàn Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù, nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì; ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀, ìwọ pè fún orin ayọ̀. Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin; ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀. Odò Ọlọ́run kún fún omi láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án. Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀ ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀; ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀, o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀. Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé, ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ Pápá tútù ní aginjù ń kan àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè. Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ; Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀, wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.