O. Daf 62:1-8
O. Daf 62:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN nikan li ọkàn mi duro jẹ dè; lati ọdọ rẹ̀ wá ni igbala mi. On nikan li apata mi ati igbala mi; on li àbo mi, emi kì yio ṣipò pada jọjọ. Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ. Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn. Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi. On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò. Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa.

O. Daf 62:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé; ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa, ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya? Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀. Inú wọn a máa dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà; òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan; ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀; OLUWA ni ààbò wa.
O. Daf 62:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ? Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.