Saamu 62:1-8

Saamu 62:1-8 YCB

Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ? Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.