O. Daf 56:8-11
O. Daf 56:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi? Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi. Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀. Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi.
O. Daf 56:8-11 Yoruba Bible (YCE)
O sá mọ gbogbo ìdààmú mi; ati bí omijé mi ti pọ̀ tó, wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ. A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́. Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi. Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀, OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀; Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù. Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?
O. Daf 56:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí? Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi. Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú OLúWA, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀: Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi: ẹ̀rù kì yóò bà mí. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?