O. Daf 56
56
Adura Igbẹkẹ le Ọlọrun
Orin Dafidi, nigbati awọn ara Filistia mu u ni Gati.
1ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi: nitoriti enia nfẹ gbe mi mì; o mba mi jà lojojumọ, o nni mi lara.
2Awọn ọta mi nfẹ igbe mi mì lojojumọ: nitori awọn ti nfi igberaga ba mi ja pọ̀.
3Nigbati ẹ̀ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ.
4Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀, Ọlọrun li emi o gbẹkẹ mi le, emi kì yio bèru: kili ẹran-ara le ṣe si mi.
5Lojojumọ ni nwọn nlọ́ ọ̀rọ mi: ibi ni gbogbo ìro inu wọn si mi:
6Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi.
7Nwọn ha le ti ipa aiṣedede là? ni ibinu, bi awọn enia na lulẹ̀, Ọlọrun.
8Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi?
9Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi.
10Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀.
11Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi.
12Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ.
13Nitoripe iwọ li o ti gbà ọkàn mi lọwọ ikú: iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mi lọwọ iṣubu? ki emi ki o le ma rìn niwaju Ọlọrun ni imọlẹ awọn alãye?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 56: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.