O. Daf 54:1-7
O. Daf 54:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi. Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn. Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro. Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ. Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara. Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.
O. Daf 54:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun, fi ipá rẹ dá mi láre. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi, àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò bìkítà fún Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi, OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró. Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi; OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run. N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ, n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀. O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi, mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.
O. Daf 54:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ. Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn. Kíyèsi i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ. Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, OLúWA, nítorí tí ó dára. Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.