O. Daf 54

54
Adura Ààbò
Orin Dafidi, nigbati awọn ara Sifi wá, ti nwọn si sọ fun Saulu pe, Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ lọdọ wa.
1ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ.
2Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi.
3Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn.
4Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro.
5Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ.
6Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara.
7Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 54: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀