O. Daf 53

53
Èrè Òmùgọ̀
1AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ nwọn si nṣe irira ẹ̀ṣẹ: kò si ẹniti o nṣe rere.
2Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun.
3Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.
4Awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ko ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun: nwọn kò si kepe Ọlọrun.
5Nibẹ ni nwọn gbe wà ni ibẹ̀ru nla nibiti ẹ̀ru kò gbe si: nitori Ọlọrun ti fún egungun awọn ti o dótì ọ ka: iwọ ti dojutì wọn, nitori Ọlọrun ti kẹgàn wọn.
6Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá? Nigbati Ọlọrun ba mu igbekun awọn enia rẹ̀ pada wá, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 53: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀