O. Daf 53:1-6
O. Daf 53:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ nwọn si nṣe irira ẹ̀ṣẹ: kò si ẹniti o nṣe rere. Ọlọrun bojuwo ilẹ lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun. Gbogbo wọn li o si pada sẹhin, nwọn si di elẽri patapata: kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan. Awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ko ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun: nwọn kò si kepe Ọlọrun. Nibẹ ni nwọn gbe wà ni ibẹ̀ru nla nibiti ẹ̀ru kò gbe si: nitori Ọlọrun ti fún egungun awọn ti o dótì ọ ka: iwọ ti dojutì wọn, nitori Ọlọrun ti kẹgàn wọn. Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá? Nigbati Ọlọrun ba mu igbekun awọn enia rẹ̀ pada wá, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.
O. Daf 53:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Kò sí Ọlọrun.” Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere. Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá, ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé, àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun. Gbogbo wọn ni ó ti yapa; tí wọn sì ti bàjẹ́, kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere, kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo. Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni? Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun, àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun. Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá, ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí! Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká; ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n. Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá! Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada, Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.
O. Daf 53:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú; kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere. Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀? Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run? Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí, nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká; ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn. Ìgbàlà Israẹli ìbá jáde wá láti Sioni! Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu yọ̀ kí inú Israẹli sì máa dùn!