O. Daf 52:1-9
O. Daf 52:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẼṢE ti iwọ fi nṣe-fefe ninu ìwa-ìka, iwọ alagbara ọkunrin? ore Ọlọrun duro pẹ titi. Ahọn rẹ ngberò ìwa-ìka; bi abẹ mimú o nṣiṣẹ ẹ̀tan. Iwọ fẹ ibi jù ire lọ; ati eke jù ati sọ ododo lọ. Iwọ fẹ ọ̀rọ ipanirun gbogbo, iwọ ahọn ẹ̀tan. Ọlọrun yio si lù ọ bolẹ lailai, yio si dì ọ mu, yio si ja ọ kuro ni ibujoko rẹ, yio si fà ọ tu kuro lori ilẹ alãye. Olododo yio ri i pẹlu, yio si bẹ̀ru, yio si ma rẹrin rẹ̀ pe, Kiyesi ọkunrin ti kò fi Ọlọrun ṣe agbara rẹ̀; bikoṣe li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ li o gbẹkẹle, o si mu ara rẹ̀ le ninu ìwa buburu rẹ̀. Ṣugbọn emi dabi igi olifi tutu ni ile Ọlọrun: emi gbẹkẹle ãnu Ọlọrun lai ati lailai. Emi o ma yìn ọ lailai nitoripe iwọ li o ṣe e: emi o si ma duro de orukọ rẹ; nitori ti o dara li oju awọn enia mimọ́ rẹ.
O. Daf 52:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu, kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru? Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun. Ò ń pète ìparun; ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè. O fẹ́ràn ibi ju ire lọ, o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ. O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, Ìwọ ẹlẹ́tàn! Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀, yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ; yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé, “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀, ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀, ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.” Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútù tí ń dàgbà ninu ilé OLUWA, mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae. N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae, nítorí ohun tí o ṣe, n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.
O. Daf 52:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin? Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo, ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run? Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dàbí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn. Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn! Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ, yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela. Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé, “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run; Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé. Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí orúkọ rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.