O. Daf 51:5-19

O. Daf 51:5-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi. Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n. Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ. Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀. Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro. Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi. Máṣe ṣa mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi mimọ́ rẹ lọwọ mi. Mu ayọ̀ igbala rẹ pada tọ̀ mi wá; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbé mi duro. Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ. Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan. Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han: Nitori iwọ kò fẹ ẹbọ, ti emi iba ru u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ kì yio gàn. Ṣe rere ni didùn inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu. Nigbana ni inu rẹ yio dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọtọ ọrẹ-ẹbọ sisun: nigbana ni nwọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.

O. Daf 51:5-19 Yoruba Bible (YCE)

Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi, ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi. O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn, kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun, kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn. Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ, má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi. Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi, kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró. Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ. Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun, ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi, n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ. OLUWA, là mí ní ohùn, n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ. Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ; ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun. Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn. Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ; tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́, ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi; nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.

O. Daf 51:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi. Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ. Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn; jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀. Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi. Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ, kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi. Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá, kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ. Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi, ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan. OLúWA, ṣí mi ní ètè mi gbogbo, àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ. Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá; Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun. Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà. Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni, ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ. Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo, pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun, nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.