O. Daf 51

51
Adura Ìdáríjì
Orin Dafidi, nigbati Natani, woli, tọ̀ ọ wá lẹhin ọ̀ran Batṣeba.
1ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ìrọnu ọ̀pọ ãnu rẹ, nù irekọja mi nù kuro.
2Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.
3Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigbagbogbo li ẹ̀ṣẹ mi si mbẹ niwaju mi.
4Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ.
5Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi.
6Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n.
7Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ.
8Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀.
9Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro.
10Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi.
11Máṣe ṣa mi tì kuro niwaju rẹ; ki o má si ṣe gbà Ẹmi mimọ́ rẹ lọwọ mi.
12Mu ayọ̀ igbala rẹ pada tọ̀ mi wá; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbé mi duro.
13Nigbana li emi o ma kọ́ awọn olurekọja li ọ̀na rẹ: awọn ẹlẹṣẹ yio si ma yipada si ọ.
14Ọlọrun, gbà mi lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi: ahọn mi yio si ma kọrin ododo rẹ kikan.
15Oluwa, iwọ ṣi mi li ète; ẹnu mi yio si ma fi iyìn rẹ han:
16Nitori iwọ kò fẹ ẹbọ, ti emi iba ru u: inu rẹ kò dùn si ọrẹ-ẹbọ sisun.
17Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkàn: irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ kì yio gàn.
18Ṣe rere ni didùn inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalemu.
19Nigbana ni inu rẹ yio dùn si ẹbọ ododo; pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọ̀tọtọ ọrẹ-ẹbọ sisun: nigbana ni nwọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 51: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa