O. Daf 51:1-10
O. Daf 51:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣeun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ìrọnu ọ̀pọ ãnu rẹ, nù irekọja mi nù kuro. Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigbagbogbo li ẹ̀ṣẹ mi si mbẹ niwaju mi. Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣẹ̀ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ lare, nigbati iwọ ba nsọ̀rọ, ki ara rẹ ki o le mọ́, nigbati iwọ ba nṣe idajọ. Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi. Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n. Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ. Mu mi gbọ́ ayọ̀ ati inu didùn; ki awọn egungun ti iwọ ti rún ki o le ma yọ̀. Pa oju rẹ mọ́ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi, ki iwọ ki o si nù gbogbo aiṣedede mi nù kuro. Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduroṣinṣin ṣe sinu mi.
O. Daf 51:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́. Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi! Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi. Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀, tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ, kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́, kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́. Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi, ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi. O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn, kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun, kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.
O. Daf 51:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́. Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi! Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi. Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀, kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́. Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi. Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ. Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn; jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀. Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.