O. Daf 42:1-9

O. Daf 42:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi, àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè. Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé? Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, nítorí náà mo ranti rẹ láti òkè Herimoni, ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani, ìbànújẹ́ ń já lura wọn, ìdààmú sì ń dà gììrì, wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun. Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn, ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi, àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi. Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé, “Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi? Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá?”

O. Daf 42:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run. Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè. Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run? Oúnjẹ mi ni omijé mi ní ọ̀sán àti ní òru, nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé, “Ọlọ́run rẹ dà?” Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́. Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín, Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi. Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí rẹ láti ilẹ̀ Jordani wá, láti Hermoni láti òkè Mibsari. Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀. Ní ọ̀sán ní OLúWA ran ìfẹ́ rẹ̀, àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi. Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi, “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi? Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́, nítorí ìnilára ọ̀tá?”

O. Daf 42:1-9

O. Daf 42:1-9 YBCVO. Daf 42:1-9 YBCV