O. Daf 42

42
IWE KEJI
(O. Daf 42—72)
Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú
1BI agbọnrin iti ma mi hẹlẹ si ipadò omi, Ọlọrun, bẹ̃li ọkàn mi nmi hẹlẹ si ọ.
2Ongbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alãye: nigbawo li emi o wá, ti emi o si yọju niwaju Ọlọrun.
3Omije mi li onjẹ mi li ọsan ati li oru, nigbati nwọn nwi fun mi nigbagbogbo pe, Ọlọrun rẹ dà?
4Nigbati mo ba ranti nkan wọnyi, emi tú ọkàn mi jade ninu mi: emi ti ba ọ̀pọ ijọ enia lọ, emi ba wọn lọ si ile Ọlọrun, pẹlu ohùn ayọ̀ on iyìn, pẹlu ọ̀pọ enia ti npa ọjọ mimọ́ mọ́.
5Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitori emi o sa ma yìn i sibẹ fun iranlọwọ oju rẹ̀.
6Ọlọrun mi, ori ọkàn mi tẹ̀ ba ninu mi: nitorina li emi o ṣe ranti rẹ lati ilẹ Jordani wá, ati lati Hermoni, lati òke Misari wá.
7Ibu omi npè ibu omi nipa hihó ṣiṣan-omi rẹ: gbogbo riru omi ati bibì omi rẹ bò mi mọlẹ.
8Ṣugbọn Oluwa yio paṣẹ iṣeun-ifẹ rẹ̀ nigba ọ̀san, ati li oru orin rẹ̀ yio wà pẹlu mi, ati adura mi si Ọlọrun ẹmi mi.
9Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì.
10Bi ẹnipe idà ninu egungun mi li ẹ̀gan ti awọn ọta mi ngàn mi; nigbati nwọn nwi fun mi lojojumọ pe, Ọlọrun rẹ dà?
11Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 42: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa