ORIN DAFIDI 42:1-9

ORIN DAFIDI 42:1-9 YCE

Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun. Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi, àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè. Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé? Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún. Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, nítorí náà mo ranti rẹ láti òkè Herimoni, ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani, ìbànújẹ́ ń já lura wọn, ìdààmú sì ń dà gììrì, wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun. Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn, ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi, àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi. Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé, “Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi? Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá?”

Verse Images for ORIN DAFIDI 42:1-9

ORIN DAFIDI 42:1-9 - Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.
Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,
àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.
Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?
Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,
nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,
“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,
bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:
bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,
tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́
lọ sí ilé Ọlọrun;
pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,
láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.
Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?
Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,
olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,
nítorí náà mo ranti rẹ
láti òkè Herimoni,
ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,
ìbànújẹ́ ń já lura wọn,
ìdààmú sì ń dà gììrì,
wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.
Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,
ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,
àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.

Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,
“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?
Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri
nítorí ìnilára ọ̀tá?”ORIN DAFIDI 42:1-9 - Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.
Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,
àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.
Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?
Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,
nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,
“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,
bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:
bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,
tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́
lọ sí ilé Ọlọrun;
pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,
láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.
Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?
Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?
Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,
olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.
Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,
nítorí náà mo ranti rẹ
láti òkè Herimoni,
ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,
ìbànújẹ́ ń já lura wọn,
ìdààmú sì ń dà gììrì,
wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.
Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,
ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,
àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.

Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,
“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?
Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri
nítorí ìnilára ọ̀tá?”