O. Daf 40:1-8
O. Daf 40:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi. O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ. O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke. Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ. Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe, Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi.
O. Daf 40:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA, ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi. Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun, láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀; ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta, ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀. Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu, àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa. Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n, wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà, tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA, tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn, àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa. OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa, o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá. Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ; bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe, kí n máa ròyìn wọn, wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ. O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ, ṣugbọn o là mí ní etí; o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé; a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé: mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi; mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”
O. Daf 40:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de OLúWA; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi. Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà. Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi OLúWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn. OLúWA Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọ́n ju ohun tí ènìyàn le è kà lọ. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè. Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé. Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi; Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”