O. Daf 4:1-8
O. Daf 4:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBOHÙN mi nigbati mo ba npè, Ọlọrun ododo mi: iwọ li o da mi ni ìde ninu ipọnju; ṣe ojurere fun mi, ki o si gbọ́ adura mi. Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe? Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e. Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ. Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹ nyin le Oluwa. Ẹni pupọ li o nwipe, Tani yio ṣe rere fun wa? Oluwa, iwọ gbé imọlẹ oju rẹ soke si wa lara. Iwọ ti fi ayọ̀ si mi ni inu, jù igba na lọ ti ọkà wọn ati ọti-waini wọn di pupọ̀. Emi o dubulẹ pẹlu li alafia, emi o si sùn; nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o nmu mi joko li ailewu.
O. Daf 4:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, Ọlọrun mi olùdániláre. Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú, ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi. Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀, tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri? Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é. Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀; ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ rú ẹbọ òdodo, kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?” OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára. Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn mi ju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè. N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia, nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu.
O. Daf 4:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi, Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi. Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké? Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, OLúWA ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; OLúWA yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é. Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀; Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín, ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́. Ẹ rú ẹbọ òdodo kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wa?” OLúWA, Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára, Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi ju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ. Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, OLúWA, ni o mú mi gbé láìléwu.