ORIN DAFIDI 4

4
Igbẹkẹle OLUWA
1Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
Ọlọrun mi olùdániláre.
Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,
ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi.
2Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,
tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri?
3Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,
OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,
kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.
5Ẹ rú ẹbọ òdodo,
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.#Efe 4:26
6Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”
OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.
7Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn mi
ju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè.
8N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia,
nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀