O. Daf 4

4
Igbẹkẹle OLUWA
1GBOHÙN mi nigbati mo ba npè, Ọlọrun ododo mi: iwọ li o da mi ni ìde ninu ipọnju; ṣe ojurere fun mi, ki o si gbọ́ adura mi.
2Ẹnyin ọmọ enia, ẹ o ti sọ ogo mi di itiju pẹ to? ẹnyin o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wá eke iṣe?
3Ṣugbọn ki ẹ mọ̀ pe Oluwa yà ẹni ayanfẹ sọ̀tọ fun ara rẹ̀: Oluwa yio gbọ́ nigbati mo ba kepè e.
4Ẹ duro ninu ẹ̀ru, ẹ má si ṣe ṣẹ̀; ẹ ba ọkàn nyin sọ̀rọ lori ẹní nyin, ki ẹ si duro jẹ.
5Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹ nyin le Oluwa.
6Ẹni pupọ li o nwipe, Tani yio ṣe rere fun wa? Oluwa, iwọ gbé imọlẹ oju rẹ soke si wa lara.
7Iwọ ti fi ayọ̀ si mi ni inu, jù igba na lọ ti ọkà wọn ati ọti-waini wọn di pupọ̀.
8Emi o dubulẹ pẹlu li alafia, emi o si sùn; nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o nmu mi joko li ailewu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa