O. Daf 144:12-15
O. Daf 144:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin. Ki aká wa ki o le kún, ki o ma funni li oniruru iṣura: ki awọn agutan wa ki o ma bi ẹgbẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun mẹwa ni igboro wa: Ki awọn malu wa ki o le rẹrù; ki o má si ikọlù, tabi ikolọ jade: ki o má si aroye ni igboro wa. Ibukún ni fun awọn enia, ti o mbẹ ni iru ìwa bẹ̃: nitõtọ, ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe.
O. Daf 144:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa, jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà, kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé, tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ, kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun, àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa. Kí àwọn mààlúù wa lóyún, kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ; kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí; ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.
O. Daf 144:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin. Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa: Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run OLúWA ń ṣe.