O. Daf 144:1-15

O. Daf 144:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUBUKÚN li oluwa apata mi, ẹniti o kọ́ ọwọ mi li ogun, ati ika mi ni ìja: Õre mi, ati odi-agbara mi; ile-iṣọ giga, ati olugbala mi; asà mi, ati ẹniti mo gbẹkẹle; eniti o tẹri awọn enia mi ba labẹ mi. Oluwa, kili enia, ti iwọ fi nkiye si i! tabi ọmọ enia, ti iwọ fi nronú rẹ̀! Enia dabi asan: bi ojìji ti nkọja lọ li ọjọ rẹ̀. Oluwa, tẹ̀ ọrun rẹ ba, ki o si sọ̀kalẹ: tọ́ awọn òke nla, nwọn o si ru ẽfin. Kọ manamana jade, ki o si tú wọn ka: ta ọfà rẹ ki o si dà wọn rú. Rán ọwọ rẹ lati òke wá; yọ mi, ki o si gbà mi kuro ninu omi nla, li ọwọ awọn ọmọ àjeji. Ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ọwọ ọtún wọn si jẹ ọwọ ọtún eke. Ọlọrun, emi o kọ orin titun si ọ: lara ohun ọnà orin olokùn mẹwa li emi o kọrin iyìn si ọ. On li o nfi igbala fun awọn ọba: ẹniti o gbà Dafidi iranṣẹ rẹ̀ lọwọ idà ipanilara. Yọ mi, ki o si gbà mi lọwọ awọn ọmọ àjeji, ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ati ọwọ ọtún wọn jẹ ọwọ ọtún eke: Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin. Ki aká wa ki o le kún, ki o ma funni li oniruru iṣura: ki awọn agutan wa ki o ma bi ẹgbẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun mẹwa ni igboro wa: Ki awọn malu wa ki o le rẹrù; ki o má si ikọlù, tabi ikolọ jade: ki o má si aroye ni igboro wa. Ibukún ni fun awọn enia, ti o mbẹ ni iru ìwa bẹ̃: nitõtọ, ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe.

O. Daf 144:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà, tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun. Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi, asà mi, ẹni tí mo sá di. Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀. OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀? Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀? Eniyan dàbí èémí, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ. OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín. Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká, ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè, kí o yọ mí ninu ibú omi; kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọn kún fún irọ́, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ, n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ. Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun, tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là. Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì, tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké. Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa, jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà, kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé, tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba. Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ, kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun, àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa. Kí àwọn mààlúù wa lóyún, kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ; kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa. Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí; ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.

O. Daf 144:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìyìn sí OLúWA àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà. Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi. OLúWA, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un, tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀? Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ. Tẹ ọ̀run rẹ ba, OLúWA, kí o sì sọ̀kalẹ̀; tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín. Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká; ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì. Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ. Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ Ọlọ́run; lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun. Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké. Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin. Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa: Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run OLúWA ń ṣe.