O. Daf 126:1-3
O. Daf 126:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá. Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn. Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀.
O. Daf 126:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada, ó dàbí àlá lójú wa. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀, nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé, “OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!” Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.