O. Daf 121:3-7
O. Daf 121:3-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe. Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn. Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ. Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru. Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́.
O. Daf 121:3-7 Yoruba Bible (YCE)
Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀, ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé. Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́ kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn. OLUWA ni olùpamọ́ rẹ. OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ. Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru. OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi, yóo pa ọ́ mọ́.
O. Daf 121:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé. Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn. OLúWA ni olùpamọ́ rẹ; OLúWA ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru. OLúWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́