O. Daf 121

121
OLUWA Aláàbò Wa
1EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa?
2Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye.
3On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe.
4Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn.
5Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ.
6Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru.
7Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́.
8Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 121: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀