Owe 9:13-18
Owe 9:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan. O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu. Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe, Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe, Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn. Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.
Owe 9:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n, oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀, á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ, àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé, “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!” Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé, “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn, oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.” Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀, ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.
Owe 9:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀. Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú, ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún. “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!” Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀, pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.