Owe 8:22-29
Owe 8:22-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi: Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye. Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu: Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye.
Owe 8:22-29 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí, láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà, nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn, kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko, kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀, tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú, ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé, nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀, tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀, nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá, kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀. Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà
Owe 8:22-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi ni OLúWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́; A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.