Owe 7:24-27
Owe 7:24-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀. Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa. Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.
Owe 7:24-27 Yoruba Bible (YCE)
Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀, ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀, ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.
Owe 7:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀ Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.