Owe 7

7
1ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura pẹlu rẹ.
2Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ.
3Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ.
4Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin:
5Ki nwọn ki o le pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin ẹlomiran, lọwọ ajeji ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe ipọnni.
Obinrin Oníṣekúṣe
6Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi.
7Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun,
8O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀,
9Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun:
10Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya.
11(O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀.
12Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.)
13Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe,
14Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi.
15Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ.
16Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti.
17Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi.
18Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara.
19Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin:
20O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju.
21Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa.
22On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.
23Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni.
24Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi.
25Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀.
26Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa.
27Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 7: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa