Owe 4:1-6
Owe 4:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro Nítorí náà má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀ Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí, mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi Ó kọ́ mi ó sì wí pé “Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró, pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè. Gba ọgbọ́n, gba òye, Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀ Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
Owe 4:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi. On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́.
Owe 4:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀, nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere, ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi, tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi, baba mi kọ́ mi, ó ní, “Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn, pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀. Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.