ÌWÉ ÒWE 4

4
Anfaani Tí Ó Wà ninu Ọgbọ́n
1Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín,
ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀,
2nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere,
ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi.
3Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi,
tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi,
4baba mi kọ́ mi, ó ní,
“Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn,
pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè.
5Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.
Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.
6Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,
fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.
7Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,
ohun yòówù tí o lè tún ní,
ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
8Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga,
yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra.
9Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí,
yóo sì dé ọ ní adé dáradára.”
10Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi,
kí ẹ̀mí rẹ lè gùn.
11Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n,
mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́.
12Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà,
nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ.
13Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin,
má jẹ́ kí ó bọ́,
pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.
14Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi,
má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.
15Yẹra fún un,
má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀,
ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ.
16Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi,
oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan.
17Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn,
ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn.
18Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́,
tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.
19Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri,
wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.
20Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi,
tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.
21Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú,
fi wọ́n sọ́kàn.
22Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn,
ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn.
23Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ,
nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.
24Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ,
sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè.
25Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán,
kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà.
26Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ,#Heb 12:13
gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.
27Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì,
yipada kúrò ninu ibi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa