ÌWÉ ÒWE 4:1-6

ÌWÉ ÒWE 4:1-6 YCE

Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀, nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere, ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi, tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi, baba mi kọ́ mi, ó ní, “Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn, pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀. Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.