Owe 13:20-23
Owe 13:20-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe. Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a. Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo, Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ

Owe 13:20-23 Yoruba Bible (YCE)
Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà. Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire. Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́. Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde, ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.
Owe 13:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára. Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo. Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.