Owe 13:20-23
Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe. Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a. Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo, Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ
Owe 13:20-23