Owe 13:14-20
Owe 13:14-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú. Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro. Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ. Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá. Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun. Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi. Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.
Owe 13:14-20 Yoruba Bible (YCE)
Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
Owe 13:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú. Òye pípé ń mú ni rí ojúrere Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀ Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn. Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá. Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi. Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.