ÌWÉ ÒWE 13:14-20

ÌWÉ ÒWE 13:14-20 YCE

Ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè a máa yọni ninu tàkúté ikú. Ẹni tí ó ní òye yóo rí ojurere, ṣugbọn ọ̀nà àwọn tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ìparun wọn. Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo, ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn. Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala, ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá. Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn, ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì. Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀. Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.