Owe 10:1-32

Owe 10:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀. Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú. Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu. Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá. Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni. Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà. Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun. Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀. Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun. Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun. Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun. Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn. Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ. Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni. Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n. Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori. Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n. Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀. Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye. Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u. Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun. Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ. Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru. Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe. Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye. Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro. Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.

Owe 10:1-32 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí: Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀. Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè, ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè, ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè a máa kó ìtìjú báni. Ibukun wà lórí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo, ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye, ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n. Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀, ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè, ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà. Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan, ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni. Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka, ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n. Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un. Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀, ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye. Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a, ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ, ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín, ati bí èéfín ti rí sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn, ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀, ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo. OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́, ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi. Gbọningbọnin ni olódodo yóo dúró, ṣugbọn ẹni ibi kò ní lè gbé ilẹ̀ náà. Ẹnu olódodo kún fún ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, ṣugbọn ẹnu alaiṣootọ ni a pamọ́. Olódodo mọ ohun tí ó dára láti sọ, ṣugbọn ti eniyan burúkú kò ju ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

Owe 10:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn òwe Solomoni: ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. OLúWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú. Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ, ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun. Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú. Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun. Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun. Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n. Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye. Ìbùkún OLúWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sì í fi ìdààmú sí i. Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLúWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú. Ìrètí olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo. Ọ̀nà OLúWA jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi. A kì yóò fa olódodo tu láéláé ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀. Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò. Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.