Òwe 10:1-32

Òwe 10:1-32 YCB

Àwọn òwe Solomoni: ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. OLúWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú. Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ, ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun. Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú. Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun. Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun. Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n. Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye. Ìbùkún OLúWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sì í fi ìdààmú sí i. Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́. Ìbẹ̀rù OLúWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú. Ìrètí olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo. Ọ̀nà OLúWA jẹ́ ààbò fún olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi. A kì yóò fa olódodo tu láéláé ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀. Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò. Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.