Num 35:11-12
Num 35:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀. Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.
Num 35:11-12 Yoruba Bible (YCE)
kí wọ́n yan ìlú mẹfa fún ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́.
Num 35:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sálọ síbẹ̀. Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má ba à kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.