Num 35

35
Àwọn Ìlú tí A Fún Àwọn Ọmọ Lefi
1OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,
2Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o fi ilu fun awọn ọmọ Lefi ninu ipín ilẹ-iní wọn, lati ma gbé; ki ẹnyin ki o si fi ẹbẹba-ilu fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnni yi wọn ká.
3Ki nwọn ki o ní ilu lati ma gbé; ati ẹbẹba-ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn, ati fun ohun-iní wọn, ati fun gbogbo ẹran wọn.
4Ati ẹbẹba-ilu, ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, lati odi ilu lọ sẹhin rẹ̀ ki o jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ yiká.
5Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn.
6Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn.
7Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn.
8Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.
Àwọn Ìlú-Ààbò
(Deu 19:1-13; Joṣ 20:1-9)
9OLUWA si sọ fun Mose pe,
10Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ Kenaani;
11Nigbana ni ki ẹnyin ki o yàn ilu fun ara nyin ti yio jẹ́ ilu àbo fun nyin; ki apania ti o pa enia li aimọ̀ ki o le ma sa lọ sibẹ̀.
12Nwọn o si jasi ilu àbo kuro lọwọ agbẹsan; ki ẹniti o pa enia ki o má ba kú titi yio fi duro niwaju ijọ awọn enia ni idajọ.
13Ati ninu ilu wọnyi ti ẹnyin o fi fun wọn, mẹfa yio jẹ́ ilu àbo fun nyin.
14Ki ẹnyin ki o yàn ilu mẹta ni ìha ihin Jordani, ki ẹnyin ki o si yàn ilu mẹta ni ilẹ Kenaani, ti yio ma jẹ́ ilu àbo.
15Ilu mẹfa wọnyi ni yio ma jẹ́ àbo fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ati fun atipo lãrin wọn: ki olukuluku ẹniti o ba pa enia li aimọ̀ ki o le ma salọ sibẹ̀.
16Ṣugbọn bi o ba fi ohunèlo irin lù u, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.
17Ati bi o ba sọ okuta lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: a o pa apania na.
18Tabi bi o ba fi ohun-èlo igi lù u, ti o le ti ipa rẹ̀ kú, ti o si kú, apania li on: pipa li a o pa apania na.
19Agbẹsan ẹ̀jẹ tikalarẹ̀ ni ki o pa apania na: nigbati o ba bá a, ki o pa a.
20Ṣugbọn bi o ba ṣepe o fi irira gún u, tabi ti o ba sọ nkan lù u, lati ibuba wá, ti on si kú;
21Tabi bi o nṣe ọtá, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lù u, ti on si kú: ẹniti o lù u nì pipa li a o pa a; nitoripe apania li on: agbẹsan ẹ̀jẹ ni ki o pa apania na, nigbati o ba bá a.
22Ṣugbọn bi o ba fi nkan gún u lojiji laiṣe ọtá, tabi ti o sọ ohunkohun lù u laiba dè e,
23Tabi okuta kan li o sọ, nipa eyiti enia le fi kú, ti kò ri i, ti o si sọ ọ lù u, ti on si kú, ti ki ṣe ọtá rẹ̀, ti kò si wá ibi rẹ̀:
24Nigbana ni ki ijọ ki o ṣe idajọ lãrin ẹniti o pa enia ati agbẹsan ẹ̀jẹ na, gẹgẹ bi idajọ wọnyi:
25Ki ijọ ki o si gbà ẹniti o pani li ọwọ́ agbẹsan ẹ̀jẹ, ki ijọ ki o si mú u pada lọ si ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si: ki o si ma gbé ibẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa, ti a fi oróro mimọ́ yàn.
26Ṣugbọn bi apania na ba ṣèṣi jade lọ si opinlẹ ilu àbo rẹ̀, nibiti o ti sá si;
27Ti agbẹsan ẹ̀jẹ na si ri i lẹhin opinlẹ ilu àbo rẹ̀, ti agbẹsan ẹ̀jẹ si pa apania na; on ki yio jẹbi ẹ̀jẹ:
28Nitoripe on iba joko ninu ilu àbo rẹ̀ titi di ìgba ikú olori alufa: ati lẹhin ikú olori alufa ki apania na ki o pada lọ si ilẹ iní rẹ̀.
29Ohun wọnyi ni o si jẹ́ ìlana idajọ fun nyin ni iraniran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.
30Ẹnikẹni ti o ba pa enia, lati ẹnu awọn ẹlẹri wá li a o pa apania na: ṣugbọn ẹlẹri kanṣoṣo ki yio jẹri si ẹnikan lati pa a.
31Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o máṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹmi apania, ti o jẹbi ikú: ṣugbọn pipa ni ki a pa a.
32Ki ẹnyin ki o má si ṣe gbà ohun-irasilẹ fun ẹniti o salọ si ilu àbo rẹ̀, pe ki on ki o tun pada lọ ijoko ni ilẹ na, titi di ìgba ikú alufa.
33Ẹnyin kò si gbọdọ bà ilẹ na jẹ́ ninu eyiti ẹnyin ngbé: nitoripe ẹ̀jẹ ama bà ilẹ jẹ́: a kò si le ṣètutu fun ilẹ nitori ẹ̀je ti a ta sinu rẹ̀, bikoṣe nipa ẹ̀jẹ ẹniti o ta a.
34Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 35: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa