Num 13:32-33
Num 13:32-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ. Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.
Num 13:32-33 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀, bíi tata ni a rí níwájú wọn.”
Num 13:32-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”