NỌMBA 13

13
Mose Rán Amí lọ sí Ilẹ̀ Kenaani
(Diut 1:19-33)
1OLUWA sọ fún Mose pé, 2“Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.” 3Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani. 4Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ó rán Ṣamua ọmọ Sakuri; 5láti inú ẹ̀yà Simeoni, ó rán Ṣafati ọmọ Hori; 6láti inú ẹ̀yà Juda, ó rán Kalebu, ọmọ Jefune; 7láti inú ẹ̀yà Isakari, ó rán Igali, ọmọ Josẹfu; 8láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ó rán Hoṣea ọmọ Nuni; 9láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ó rán Paliti, ọmọ Rafu; 10láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ó rán Gadieli, ọmọ Sodi; 11láti inú ẹ̀yà Josẹfu, tí í ṣe ẹ̀yà Manase, ó rán Gadi, ọmọ Susi; 12láti inú ẹ̀yà Dani, ó rán Amieli, ọmọ Gemali; 13láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ó rán Seturu, ọmọ Mikaeli; 14láti inú ẹ̀yà Nafutali, ó rán Nahibi ọmọ Fofisi; 15láti inú ẹ̀yà Gadi, ó rán Geueli ọmọ Maki.
16Orúkọ àwọn ọkunrin tí Mose rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà nìyí. Mose sì yí orúkọ Hoṣea ọmọ Nuni pada sí Joṣua.
17Mose rán wọn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Kí wọ́n tó lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà ìhà àríwá, kí ẹ tọ̀ ọ́ lọ sí ìhà gúsù ilẹ̀ Kenaani, kí ẹ wá lọ sí àwọn orí òkè. 18Ẹ wo irú ilẹ̀ tí ilẹ̀ Kenaani jẹ́, àwọn eniyan mélòó ló ń gbé ibẹ̀ ati pé báwo ni wọ́n ṣe lágbára sí. 19Ẹ ṣe akiyesi bóyá ilẹ̀ náà dára tabi kò dára, ati pé bóyá àwọn eniyan ibẹ̀ ń gbé inú àgọ́ ninu ìlú tí ó tẹ́jú tabi ìlú olódi ni ìlú wọn. 20Ẹ wò bóyá ilẹ̀ náà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú, ẹ wò ó bóyá igi wà níbẹ̀ tabi kò sí. Ẹ múra gírí kí ẹ sì mú ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀.” (Àkókò náà sì jẹ́ àkókò àkọ́so àjàrà.)
21Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati. 22Wọ́n gba ìhà gúsù gòkè lọ sí Heburoni, níbi tí àwọn ẹ̀yà Ahimani, ati ti Ṣeṣai ati ti Talimai, àwọn òmìrán ọmọ Anaki ń gbé. (A ti tẹ Heburoni dó ní ọdún meje ṣáájú Soani ní ilẹ̀ Ijipti.) 23Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣikolu, wọn gé ṣiiri àjàrà kan tí ó ní èso. Ṣiiri àjàrà yìí tóbi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn meji ni wọ́n fi ọ̀pá gbé e. Wọ́n sì mú èso pomegiranate ati èso ọ̀pọ̀tọ́ wá pẹlu. 24Wọ́n sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣikolu, nítorí ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti gé ìtì èso àjàrà.
25Lẹ́yìn tí wọ́n ti wo ilẹ̀ náà fún ogoji ọjọ́, àwọn amí náà pada. 26Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n. 27Wọ́n sọ fún Mose pé, “A ti wo ilẹ̀ tí ẹ rán wa lọ wò, a sì rí i pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati fún oyin ni. Ó lẹ́tù lójú lọpọlọpọ; èso inú rẹ̀ nìwọ̀nyí. 28Ṣugbọn àwọn eniyan tí ń gbé inú rẹ̀ lágbára, ìlú ńláńlá tí wọ́n sì mọ odi yíká ni ìlú wọn. Ohun tí ó wá burú ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, a rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀. 29Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.”
30Ṣugbọn Kalebu pa àwọn eniyan náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á lọ nisinsinyii láti gba ilẹ̀ náà, nítorí a lágbára tó láti borí àwọn eniyan náà.”
31Àwọn amí yòókù ní, “Rárá o! A kò lágbára tó láti gbógun ti àwọn eniyan náà, wọ́n lágbára jù wá lọ.” 32Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀. 33A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀, bíi tata ni a rí níwájú wọn.” #Jẹn 6:4

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀