Num 13:26-33

Num 13:26-33 Yoruba Bible (YCE)

Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A ti wo ilẹ̀ tí ẹ rán wa lọ wò, a sì rí i pé ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára, tí ó kún fún wàrà ati fún oyin ni. Ó lẹ́tù lójú lọpọlọpọ; èso inú rẹ̀ nìwọ̀nyí. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ń gbé inú rẹ̀ lágbára, ìlú ńláńlá tí wọ́n sì mọ odi yíká ni ìlú wọn. Ohun tí ó wá burú ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, a rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀. Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.” Ṣugbọn Kalebu pa àwọn eniyan náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á lọ nisinsinyii láti gba ilẹ̀ náà, nítorí a lágbára tó láti borí àwọn eniyan náà.” Àwọn amí yòókù ní, “Rárá o! A kò lágbára tó láti gbógun ti àwọn eniyan náà, wọ́n lágbára jù wá lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ wò. Wọ́n ní, “Ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn eniyan inú rẹ̀ ni ilẹ̀ náà, gbogbo àwọn tí a rí níbẹ̀ ṣígbọnlẹ̀. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán ọmọ Anaki níbẹ̀, bíi tata ni a rí níwájú wọn.”

Num 13:26-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá Òkun àti ní etí bèbè Jordani.” Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.” Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.” Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀. A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”