Mak 13:1-13
Mak 13:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi! Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? Kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ. Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ? Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ: Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.
Mak 13:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!” Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.” Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣẹ ati pé kí ni àmì tí yóo hàn kí gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tó rí bẹ́ẹ̀?” Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ. Ọpọlọpọ yóo wá ní orúkọ mi tí wọ́n yóo wí pé àwọn ni Kristi. Wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí. “Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn. Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná. Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yóo ṣe ikú pa ara wọn; bẹ́ẹ̀ ni baba yóo ṣe sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóo tàpá sí àwọn òbí wọn, wọn yóo sì pa wọ́n. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun ni a óo gbàlà.
Mak 13:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí Jesu ti ń jáde láti inú tẹmpili ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.” Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.” Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ ààmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?” Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ. Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jì ní ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.