MAKU 13

13
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Wíwó Tẹmpili
(Mat 24:1-2; Luk 21:5-6)
1Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!”
2Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.”
Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora
(Mat 24:3-14; Luk 21:7-19)
3Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé, 4“Sọ fún wa, nígbà wo ni àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣẹ ati pé kí ni àmì tí yóo hàn kí gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tó rí bẹ́ẹ̀?”
5Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ. 6Ọpọlọpọ yóo wá ní orúkọ mi tí wọ́n yóo wí pé àwọn ni Kristi. Wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ. 7Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé. 8Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí.
9“Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.#Mat 10:17-20; Luk 12:11-12 10Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná. 11Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. 12Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yóo ṣe ikú pa ara wọn; bẹ́ẹ̀ ni baba yóo ṣe sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóo tàpá sí àwọn òbí wọn, wọn yóo sì pa wọ́n. 13Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun ni a óo gbàlà.#Mat 10:22
Àkókò Ìpọ́njú Ńlá
(Mat 24:15-28; Luk 21:20-24)
14“Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè.#Dan 9:27; 11:31; 12:11; 1 Makab 1:54; 6:7 15Nígbà tí ẹni tí ó wà ní òkè ilé bá sọ̀kalẹ̀, kí ó má ṣe wọ ilé lọ láti mú ohunkohun jáde. 16Kí alágbàro ní oko má ṣe dúró mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀.#Luk 17:31 17Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ náà yóo jẹ́ fún àwọn aboyún ati àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní àkókò náà. 18Kí ẹ gbadura kí ó má jẹ́ àkókò tí òtútù mú pupọ. 19Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae.#Dan 12:1; Ifi 7:14 20Bí kò bá jẹ́ pé Oluwa dín àkókò náà kù, ẹ̀dá kankan kì bá tí kù láàyè. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́ tí Ọlọrun yàn, ó dín àkókò rẹ̀ kù.
21“Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́. 22Nítorí àwọn Kristi èké ati àwọn wolii èké yóo dìde, wọn yóo máa ṣe iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ. Wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ, bí ó bá ṣeéṣe. 23Ṣugbọn ẹ̀yin, ní tiyín, ẹ ṣọ́ra. Mo ti sọ ohun gbogbo fun yín tẹ́lẹ̀.
Dídé Ọmọ-Eniyan
(Mat 24:29-31; Luk 21:25-28)
24“Ní àkókò náà, lẹ́yìn ìpọ́njú yìí oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.#a Ais 13:10; Joẹl 2:10, 31; 3:15; Ifi 6:12; b Ais 13:10; Isi 32:7 25Àwọn ìràwọ̀ yóo máa já bọ́ láti ojú ọ̀run, a óo wá mi gbogbo àwọn ogun ọ̀run.#a Ais 34:4; Ifi 6:13 b Joẹl 2:10 26Nígbà náà ni wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ ninu awọsanma pẹlu agbára ńlá ati ògo.#Dan 7:13; Ifi 1:7 27Yóo wá rán àwọn angẹli láti lọ kó àwọn àyànfẹ́ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé, láti òpin ayé títí dé òpin ọ̀run.
Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́
(Mat 24:32-35; Luk 21:29-33)
28“Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó rú ewé, ẹ mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ ìtòsí. 29Bákan náà nígbà tí ẹ bá rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, kí ẹ mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan wà nítòsí, ó fẹ́rẹ̀ dé. 30Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹ. 31Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.
Nígbà Wo ni Àkókò Náà?
(Mat 24:36-44)
32“Ṣugbọn ní ti ọjọ́ ati wakati náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀, àwọn angẹli kò mọ̀, Ọmọ pàápàá kò mọ̀, àfi Baba.#Mat 24:36 33Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nà#13:33 Ọpọlọpọ ninu àwọn Bibeli àtijọ́ fi kún gbolohun yìí pé: Kí ẹ sì máa gbadura. nítorí ẹ kò mọ wakati náà. 34Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.#Luk 12:36-38 35Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú. 36Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun. 37Ohun tí mò ń wí fun yín ni mò ń wí fún gbogbo eniyan: ẹ máa ṣọ́nà.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

Videos for MAKU 13