MAKU 12

12
Òwe Nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà
(Mat 21:33-46; Luk 20:9-19)
1Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀.#Ais 5:1-2 2Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn. 3Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo. 4Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í. 5Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn. 6Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’ 7Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’ 8Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n bá wọ́ ọ jù sẹ́yìn ọgbà àjàrà.
9“Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóo ṣe? Yóo wá, yóo pa àwọn alágbàro wọ̀n-ọn-nì, yóo sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàro mìíràn. 10Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé,
‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀
ni ó di pataki igun ilé.
11Iṣẹ́ Oluwa ni èyí,
Ìyanu ni ó jẹ́ ní ojú wa.’ ”#O. Daf 118:22-23
12Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ.
Ìbéèrè nípa Owó-orí ti Ìjọba Kesari
(Mat 22:15-22; Luk 20:20-26)
13Wọ́n rán àwọn kan ninu àwọn Farisi ati àwọn ọ̀rẹ́ Hẹrọdu sí i láti lọ gbọ́ tẹnu rẹ̀. 14Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”
15Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka#12:15 Ní Giriki orúkọ owó yìí ni denariusi. Denariusi kan ni owó ojúmọ́ òṣìṣẹ́ kan. kan wá fún mi kí n rí i.”
16Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?”
Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”
17Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.”
Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀.
Ìbéèrè Nípa Ajinde
(Mat 22:23-33; Luk 20:27-40)
18Ní àkókò náà, àwọn Sadusi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n ní kò sí ohun tí ń jẹ́ ajinde òkú.) Wọ́n ní,#A. Apo 23:8 19“Olùkọ́ni, Mose kọ òfin kan fún wa pé bí ọkunrin kan bá kú, tí ó fi aya sílẹ̀, tí kò bá ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kí ó lè ní ọmọ ní orúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.#Diut 25:5 20Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà, èyí ekinni fẹ́ aya, ó kú láì ní ọmọ, 21Ekeji ṣú aya rẹ̀ lópó, ṣugbọn òun náà kú láì ní ọmọ. Ẹkẹta náà kú láì ní ọmọ. 22Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣá ṣe kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo wọn, obinrin náà kú. 23Nígbà tí ó bá di ọjọ́ ajinde, iyawo ta ni obinrin yìí yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ni ó ti fi ṣe aya?”
24Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun? 25Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí. 26Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’#Eks 3:6 27Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.”
Òfin Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
(Mat 22:34-40; Luk 10:25-28)
28Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?”
29Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa. 30Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’#Diut 6:4-5 31Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.”#Lef 19:18
32Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’;#Diut 4:35 33ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.”#Hos 6:6
34Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.”#Luk 10:25-28
Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.
Ìbéèrè Jesu Nípa Ọmọ Dafidi
(Mat 22:41-46; Luk 20:41-44)
35Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi? 36Dafidi fúnrarẹ̀ wí nípa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ pé,#O. Daf 110:1
‘Oluwa wí fún Oluwa mi pé:
Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí n óo fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.’
37Nígbà tí Dafidi fúnrarẹ̀ pè é ní ‘Oluwa,’ báwo ni ó ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Pẹlu ayọ̀ ni ọpọlọpọ eniyan ń fetí sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Jesu ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Amòfin
(Mat 23:1-36; Luk 20:45-47)
38Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé. 39Wọ́n fẹ́ràn ipò ọlá nínú sinagọgu ati ní ibi àsè. 40Wọ́n a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gbadura gígùn nítorí àṣehàn. Ìdájọ́ tí wọn yóo gbà yóo le pupọ.”
Ọrẹ Opó Kan
(Luk 21:1-4)
41Bí Jesu ti jókòó lọ́kàn-ánkán àpótí owó, ó ń wò bí ọpọlọpọ eniyan ti ń dá owó sinu àpótí. Ọpọlọpọ àwọn ọlọ́rọ̀ ń dá owó pupọ sinu àpótí owó. 42Nígbà náà ni talaka opó kan wá, ó dá eépìnnì#12:42 Giriki: Lepita. meji tí ó jẹ́ kọbọ#12:42 Giriki: Kọdirantesi. kan sinu àpótí. 43Jesu wá tọ́ka sí èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Mo ń wí fun yín gbangba pé opó talaka yìí dá owó ju gbogbo àwọn tí ó dá owó sinu àpótí lọ. 44Nítorí ninu ọpọlọpọ ọrọ̀ ni àwọn yòókù ti mú ohun tí wọ́n dá, ṣugbọn òun, ninu àìní rẹ̀, ó dá gbogbo ohun tí ó ní, àní gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU 12: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀