Bí Jesu ti ń jáde láti inú tẹmpili ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”
Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ ààmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ. Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jì ní ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.
“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.
“Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.