Mak 13:1-13

Mak 13:1-13 YBCV

BI o si ti nti tẹmpili jade, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wipe, Olukọni, wò irú okuta ati irú ile ti o wà nihinyi! Jesu si dahùn wi fun u pe, Iwọ ri ile nla wọnyi? Kì yio si okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a kì yio wó lulẹ. Bi o si ti joko lori òke Olifi ti o kọju si tẹmpili, Peteru ati Jakọbu, ati Johanu ati Anderu, bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ? Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ: Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ. Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.

Àwọn fídíò fún Mak 13:1-13