Lef 7:28-38

Lef 7:28-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹniti o ba ru ẹbọ alafia rẹ̀ si OLUWA, ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ tọ̀ OLUWA wá ninu ẹbọ alafia rẹ̀: Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. Ki alufa na ki o sun ọrá na lori pẹpẹ: ṣugbọn ki igẹ̀ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀. Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin. Ninu awọn ọmọ Aaroni ẹniti o rubọ ẹ̀jẹ ẹbọ alafia, ati ọrá, ni ki o ní itan ọtun fun ipín tirẹ̀. Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli. Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA; Ti OLUWA palaṣẹ lati fi fun wọn lati inu awọn ọmọ Israeli, li ọjọ́ ti o fi oróro yàn wọn. Ìlana lailai ni iraniran wọn. Eyi li ofin ẹbọ sisun, ti ẹbọ ohunjijẹ, ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ti ẹbọ ẹbi, ati ti ìyasimimọ́, ati ti ẹbọ alafia; Ti OLUWA palaṣẹ fun Mose li òke Sinai, li ọjọ́ ti o paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá fun OLUWA ni ijù Sinai.

Lef 7:28-38 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, yóo mú ẹbọ náà wá fún OLUWA. Ninu ẹbọ alaafia rẹ̀, ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Alufaa yóo sun ọ̀rá ẹran náà lórí pẹpẹ, ṣugbọn àyà rẹ̀ yóo jẹ́ ti Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ óo fún alufaa ní itan ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ lára ẹbọ alaafia yín. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ Aaroni tí ó bá fi ẹ̀jẹ̀ ati ọ̀rá ẹran náà rúbọ ni ó ni itan ọ̀tún ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli. Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.” Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia; tí OLUWA paláṣẹ fún Mose, ní orí òkè Sinai ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti mú ẹbọ wọn wá fún òun OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai.

Lef 7:28-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún OLúWA. Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún OLúWA, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú OLúWA bí ọrẹ fífì. Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà. Ọmọ Aaroni ẹni tí ó rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’ ” Èyí ni ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ẹbọ tí a finá sun sí OLúWA lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn wá láti sin OLúWA gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Lọ́jọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLúWA ti pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa fún wọn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ìgbà gbogbo fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Nítorí náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìlànà fún ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi, ìfinijoyè àlùfáà àti ẹbọ àlàáfíà èyí tí OLúWA fún Mose lórí òkè Sinai lọ́jọ́ tí OLúWA pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wọn wá fún OLúWA ni ijù Sinai.