Lef 7

7
Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi
1EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni.
2Ni ibi ti nwọn gbé pa ẹbọ sisun ni ki nwọn ki o pa ẹbọ ẹbi: ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ yiká.
3Ki o si fi gbogbo ọrá inu rẹ̀ rubọ; ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati ọrá ti o bò ifun lori,
4Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro:
5Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹbi ni.
6Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni.
7Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i.
8Ati alufa ti nru ẹbọ sisun ẹnikẹni, ani alufa na ni yio ní awọ ẹran ẹbọ sisun, ti o ru fun ara rẹ̀.
9Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ati gbogbo eyiti a yan ninu apẹ, ati ninu awopẹtẹ, ni ki o jẹ́ ti alufa ti o ru u.
10Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò, ati gbigbẹ, ni ki gbogbo awọn ọmọ Aaroni ki o ní, ẹnikan bi ẹnikeji rẹ̀.
Ẹbọ Alaafia
11Eyi si ni ofin ẹbọ alafia, ti on o ru si OLUWA.
12Bi o ba mú u wá fun idupẹ́, njẹ ki o mú adidùn àkara alaiwu wá ti a fi oróro pò, pẹlu ẹbọ ọpẹ́ rẹ̀, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati adidùn àkara iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, ti a din.
13Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́.
14Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia.
15Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀.
16Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu:
17Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun.
18Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
19Ẹran ti o ba si kàn ohun aimọ́ kan, a kò gbọdọ jẹ ẹ; sisun ni ki a fi iná sun u. Ṣugbọn ẹran na ni, gbogbo ẹniti o mọ́ ni ki o jẹ ninu rẹ̀.
20Ṣugbọn ọkàn na ti o ba jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ti on ti ohun aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
21Pẹlupẹlu ọkàn na ti o ba fọwọkàn ohun aimọ́ kan, bi aimọ́ enia, tabi ẹranko alaimọ́, tabi ohun irira elẽri, ti o si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
22OLUWA si sọ fun Mose pe,
23Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ọrákọra akọmalu, tabi ti agutan, tabi ti ewurẹ.
24Ati ọrá ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, ati ọrá eyiti ẹranko fàya, on ni ki a ma lò ni ilò miran: ṣugbọn ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ.
25Nitoripe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọrá ẹran, ninu eyiti enia mú rubọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ani ọkàn ti o ba jẹ ẹ on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
26Pẹlupẹlu ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, iba ṣe ti ẹiyẹ tabi ti ẹran, ninu ibugbé nyin gbogbo.
27Ọkànkọkàn ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
28OLUWA si sọ fun Mose pe,
29Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹniti o ba ru ẹbọ alafia rẹ̀ si OLUWA, ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ tọ̀ OLUWA wá ninu ẹbọ alafia rẹ̀:
30Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.
31Ki alufa na ki o sun ọrá na lori pẹpẹ: ṣugbọn ki igẹ̀ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀.
32Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin.
33Ninu awọn ọmọ Aaroni ẹniti o rubọ ẹ̀jẹ ẹbọ alafia, ati ọrá, ni ki o ní itan ọtun fun ipín tirẹ̀.
34Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli.
35Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA;
36Ti OLUWA palaṣẹ lati fi fun wọn lati inu awọn ọmọ Israeli, li ọjọ́ ti o fi oróro yàn wọn. Ìlana lailai ni iraniran wọn.
37Eyi li ofin ẹbọ sisun, ti ẹbọ ohunjijẹ, ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ti ẹbọ ẹbi, ati ti ìyasimimọ́, ati ti ẹbọ alafia;
38Ti OLUWA palaṣẹ fun Mose li òke Sinai, li ọjọ́ ti o paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá fun OLUWA ni ijù Sinai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Lef 7: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀